IWURE (PRAYERS)

These prayers should be said at the start and at the end of each day. They are used to set a positive course for the activities of the current day and prepare you for the activities of tomorrow.

IWURE 1

Olódùmarè àwa omo rę dé,

Adé láti wá gba ìre tiwa,

Asìn ńbè ọ lórúkọ odù mérìndínlógún

Kí o gbó ìre tòní yí

Bí o bá gbọ kí o múu şę,

Kí o máa śọ Baba wa

Kí o máa śọ Ìyá wa

Kí o máa śọ Aya/Ọkọ wa

Kí o máa śọ Ọmọ wa,

Kí o máa śọ Alábàá gbélé àti òré wa

Títí tófi mó ibi tí aní ẹni dé

Pàápàá àti àwọn mòlébí wa

Afi ọlójó òní bè ó

Kí o fi yè dénú

Kí o fi yè dékùn

Kí o fi yè dé gbogbo ara

Bàbá awa Ọmọ rẹ là ń pè ó

Èlà ìború Èlà bòyè Èlà boşíşe

PRAYER 1 (Opening)

Olodumare we, the children, have come

We have come to get our blessings for today

We are begging you in the name of all the 16 major odu

That you should listen to the prayer of the day

When you hear our prayer, please grant our request

Protect our Fathers

Protect our Mothers

Protect our Wives/Husbands

Protect our Children

Protect our Neighbors and Friends

And extend your protection to all our well-wishers

Most especially our relatives

We beg you in the name of the Orisha that rules today

For you to be mindful of what we are doing

For you to be mindful of all our proceedings

For you to be mindful of all our generalities

Father, we the children are calling upon you

Èlà ìború Èlà bòyè Èlà boşíşe

ORIN 1

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi

Gbogbo ìre tí mo bá mòmò wí òò

Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà

Yío gbàá òò

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi

SONG 1 (Repeat of Opening)

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my voice

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth,

All my positive affirmation and prayers

Will be accepted by the IRÚNMỌLÈ

Absolutely accepted

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth

IWURE 2

OLÓDÙMARÈ Oba Àjíkí

ÒDÙMÀRÈ Ọba Àjígè

Ògègé Ọba tó gbé ilé Ayé dúró

Ògbàgbà ńlá Ọba tó lòde òrun

Bàbá àwa Ọmọ rẹ là ń pè ó

Láti wá gba ìre tiwa

OLÓDÙMARÈ tatí were kí o wá gbáhǜn àwa Ọmọ rẹ

Bí o bá gbó kí o múu şẹ

Ibi kíbi tí abá ńlọ máà jékí a bó sówó ikú

Gbogbo ojúmó tóbá ti nmó ire ni kó máajé fún wa

Máajé kí Èsù ó báwa jà

Abè ó lórúkọ ÒRÌŞÀ Àkúnlè bọ

Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Àbèrè bo

Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Ádúró bo

Kí ààbo rẹ èti ìràńwó rẹ ó máa báwa gbé ní gbogbo ọjó

Kí ó şẹ béè! Kí ó şẹ béè!! Kí ó şẹ béè!!!

Èlà ìború! Èlà bòyè!! Èlà boşíşe.!!!

PRAYER 2 (Closing)

Olodumare the King of The Begining

Odumare, the King of Adulation

The axis of equilibrium on which the world pivots

The King that rules the great beyond

Father, we the children are calling upon you

For you to accept our prayer.

Olodumare listen to the joyful voice of your children

When you listen, will you please accept our request

Wherever we go, make our journey safe and prevent our death

All of the beautiful mornings that we will see, let them be protected for us

Absolute guidance of Èsù protection.

We appeal you in the name of all the Orisha we kneel down to revere

And appeal to you in the name of all the Orisha we bend down to revere

And appeal to you in the name of all the Orisha we stand to revere

Let your guidance and your assistance be with us forever and ever

So shall it be! So shall it be!! So shall it be!!!

Èlà ìború! Èlà bòyè!! Èlà boşíşe.!!!

ORIN 1

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi

Gbogbo ìre tí mo bá mòmò wí òò

Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà

Yío gbàá òò

Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi

SONG 1 (Repeat of Opening)

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my voice

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth,

All my positive affirmation and prayers

Will be accepted by the IRÚNMỌLÈ

Absolutely accepted

Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth

ORIN 3

Bí mo dúró, bí mo súre

Bi mo bèrè, bí mo súre

Bi mo jòkó, bí mo súre

Ìre tí mo sù

ori ti gbó

SONG 3 (Closing)

If I’m standing, I’m praying

If I’m bending, I’m praying

If I’m sitting, I’m praying

All my prayer

Has been accepted