Ile Ategbe Logo

CSS Menu Top Css3Menu.com

Classes & Workshops | Prayer Calendar | Iwure (Prayers) | 16 Major ODU IFA

Iwure (Prayers)
Heading Divider

These prayers should be said at the start and at the end of each day. They are used to set a positive course for the activities of the current day and prepare you for the activities of tomorrow.Prayer image

 

IWURE (1)

OPENING PRAYER (1)
Olódùmarè àwa omo rę dé, Olodumare we, the children, have come
Adé láti wá gba ìre tiwa, We have come to receive our blessings for today
Asìn ńbè ọ lórúkọ odù mérìndínlógún We ask in the name of all the 16 major odu
Kí o gbó ìre tòní yí That you should listen to the prayer of the day
Bí o bá gbọ kí o múu  şę, When you hear our prayer, please grant our request
Kí o máa śọ Baba wa Protect our Fathers
Kí o máa śọ Ìyá wa Protect our Mothers
Kí o máa śọ Aya tabi Ọkọ wa Protect our Wives or Husbands
Kí o máa śọ Ọmọ wa, Protect our Children
Kí o máa śọ Alábàá gbélé àti òré wa Protect our Neighbors and Friends
Títí tófi mó ibi tí aní ẹni dé And extend your protection to all of our well-wishers
Pàápàá àti àwọn mòlébí wa Most especially our relatives
Afi ọlójó òní bè ó We ask in the name of the Orisha that rules today
Kí o fi yè dénú For you to be mindful of what we are doing
Kí o fi yè dékùn For you to be mindful of all our proceedings
Kí o fi yè dé gbogbo ara For you to be mindful of all our generalities
Bàbá awa Ọmọ rẹ là ń pè ó Father, we the children are calling upon you
Èlà Ìború Èlà Bòyè Èlà Boşíşe Èlà Ìború Èlà Bòyè Èlà Boşíşe
 

ORIN (1)

SONG TO ACCOMPANY OPENING PRAYER (1)
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò The power of ÒRÌŞÀ positive energy is in my mouth!
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi The power of ÒRÌŞÀ positive energy is in my voice,
Gbogbo ìre tí mo bá mòmò wí òò All my positive affirmation and prayers!
Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà Will be accepted by the IRÚNMỌLÈ
Yío gbàá òò Absolutely accepted!
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth,
 

IWURE 2

CLOSING PRAYER (2)
OLÓDÙMARÈ Oba Àjíkí Olodumare the King of The Begining
ÈDÙMÀRÈ Ọba Àjígè Edumare, the King of Adulation
Ògègé Ọba tó gbé ilé Ayé dúró The axis of equilibrium on which the world pivots
Ògbàgbà ńlá Ọba tó lòde òrun The King that rules the great beyond
Bàbá àwa Ọmọ rẹ là ń pè ó Father, we the children are calling upon you
Láti wá gba ìre tiwa For you to accept our prayer.
OLÓDÙMARÈ tatí were kí o wá gbáhǜn  àwa Ọmọ rẹ Olodumare listen to the joyful voice of your children
Bí o bá gbó kí o múu şẹ When you listen, will you please accept our request
Ibi kíbi tí abá ńlọ máà jékí a bó sówó ikú Wherever we go, make our journey safe and prevent our death
Gbogbo ojúmó tóbá ti nmó ire ni kó máajé fún wa All of the beautiful mornings that we will see, let them be protected for us
Máajé kí Èsù ó báwa jà Absolute guidance of  Èsù protection.
Abè ó lórúkọ ÒRÌŞÀ Àkúnlè bọ We appeal you in the name of all the Orisha we kneel down to revere
Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Àbèrè bo And appeal to you in the name of all the Orisha we bend down to revere
Àti lórúkọ ÒRÌŞÀ Ádúró bo And appeal to you in the name of all the Orisha we stand to revere
Kí ààbo rẹ èti ìràńwó rẹ ó máa báwa gbé ní gbogbo ọjó Let your guidance and assistance be with us forever and ever
Kí ó şẹ béè! Kí ó şẹ béè!! Kí ó şẹ béè!!! So shall it be! So shall it be!! So shall it be!!!
Èlà Ìború Èlà Bòyè Èlà Boşíşe Èlà Ìború Èlà Bòyè Èlà Boşíşe
 

ORIN 2

SONG TO ACCOMPANY CLOSING PRAYER
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi oò The power of ÒRÌŞÀ positive energy is in my mouth!
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi The power of ÒRÌŞÀ positive energy is in my voice,
Gbogbo ìre tí mo bá mòmò wí òò All my positive affirmation and prayers!
Ni IRÚNMỌLÈ o gbàà Will be accepted by the IRÚNMỌLÈ
Yío gbàá òò Absolutely accepted!
Àşẹ ÒRÌŞÀ lénu mi Acceptance of ÒRÌŞÀ blessings from my mouth,
 

ORIN 3

ANOTHER SONG TO ACCOMPANY CLOSING PRAYER
Bí mo dúró, bí mo súre If I'm  standing, I'm praying
Bi mo bèrè, bí mo súre If I'm bending, I'm praying
Bi mo jòkó, bí mo súre If I'm sitting, I'm praying
Ìre tí mo sù All my prayers
ori ti gbó Have been accepted